Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oni 10:1-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OKÚ eṣinṣin o mu ororo-ikunra alapolu bajẹ ki o ma run õrùn buburu: bẹ̃ni wère diẹ wuwo jù ọgbọ́n ati ọlá lọ.

2. Aiya ọlọgbọ́n mbẹ li ọwọ ọtún rẹ̀; ṣugbọn aiya aṣiwère li ọwọ òsi rẹ̀.

3. Ati pẹlu nigbati ẹniti o ṣiwère ba nrìn li ọ̀na, ọgbọ́n rẹ̀ a fò lọ, on a si wi fun olukuluku enia pe aṣiwère li on.

4. Bi ọkàn ijoye ba ru si ọ, máṣe fi ipò rẹ silẹ; nitoripe itũbá ama tù ẹ̀ṣẹ nla.

5. Buburu kan mbẹ ti mo ri labẹ õrùn, bi ìṣina ti o ti ọdọ awọn ijoye wá.

6. A gbe aṣiwère sipò ọlá, awọn ọlọrọ̀ si joko nipò ẹhin.

7. Mo ri awọn ọmọ-ọdọ lori ẹṣin, ati awọn ọmọ-alade nrìn bi ọmọ-ọdọ ni ilẹ.

8. Ẹniti o wà iho ni yio bọ́ sinu rẹ̀; ati ẹniti o si njá ọgbà tútù, ejo yio si bù u ṣán.

9. Ẹnikan ti o nyi okuta ni yio si ti ipa rẹ̀ ni ipalara; ati ẹniti o si nla igi ni yio si wu li ewu.

10. Bi irin ba kújú, ti on kò si pọn oju rẹ̀, njẹ ki on ki o fi agbara si i; ṣugbọn ère ọgbọ́n ni lati fi ọ̀na hàn.

11. Nitõtọ bi ejo ba bu ni ṣán lainitùju; njẹ ère kì yio si fun onitùju.

12. Ọ̀rọ ẹnu ọlọgbọ̀n li ore-ọfẹ; ṣugbọn ète aṣiwère ni yio gbe ara rẹ̀ mì.

13. Ipilẹṣẹ ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ ni wère: ati opin ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ ni isinwin iparun.

14. Aṣiwère pẹlu kún fun ọ̀rọ pupọ: enia kò le sọ ohun ti yio ṣẹ; ati ohun ti yio wà lẹhin rẹ̀, tali o le wi fun u?

15. Lãla aṣiwère da olukuluku wọn li agara, nitoriti kò mọ̀ bi a ti lọ si ilu.

Ka pipe ipin Oni 10