Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Sol 5:7-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Awọn oluṣọ ti nrìn ilu kiri ri mi, nwọn lù mi, nwọn sì ṣa mi lọgbẹ, awọn oluṣọ gbà iborùn mi lọwọ mi.

8. Mo fi nyin bu, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, bi ẹnyin ba ri olufẹ mi, ki ẹ wi fun u pe, aisan ifẹ nṣe mi.

9. Kini olufẹ rẹ jù olufẹ miran lọ, iwọ arẹwà julọ ninu awọn obinrin? kini olufẹ rẹ jù olufẹ miran ti iwọ fi nfi wa bú bẹ̃?

10. Olufẹ mi funfun, o si pọn, on ni ọlá jù ọ̀pọlọpọ lọ.

11. Ori rẹ̀ dabi wura ti o dara julọ, ìdi irun rẹ̀ dabi imọ̀ ọpẹ, o si du bi ẹiyẹ iwò.

12. Oju rẹ̀ dabi àdaba li ẹba odò, ti a fi wàra wẹ̀, ti o si ngbe inu alafia.

13. Ẹrẹ̀kẹ rẹ̀ dabi ebè turari, bi olõrùn didùn, ète rẹ̀ bi itanna lili, o nkán ojia olõrùn didùn.

14. Ọwọ rẹ̀ dabi oruka wura ti o tò ni berili yika, ara rẹ̀ bi ehin-erin didán ti a fi saffire bò.

15. Itan rẹ̀ bi ọwọ̀n marbili, ti a gbe ka ihò ìtẹbọ wura daradara; ìwo rẹ̀ dabi Lebanoni, titayọ rẹ̀ bi igi kedari.

16. Ẹnu rẹ̀ dùn rekọja: ani o wunni patapata. Eyi li olufẹ mi, eyi si li ọrẹ mi, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu.

Ka pipe ipin O. Sol 5