Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Sol 2:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EMI ni itanná eweko Ṣaroni, ati itanná lili awọn afonifoji.

2. Bi itanná lili lãrin ẹgún, bẹ̃li olufẹ mi ri lãrin awọn ọmọbinrin.

3. Bi igi eleso lãrin awọn igi igbẹ, bẹ̃li olufẹ mi ri lãrin awọn ọmọkunrin. Emi fi ayọ̀ nla joko labẹ ojiji rẹ̀, eso rẹ̀ si dùn mọ mi li ẹnu.

4. O mu mi wá si ile ọti-waini, Ifẹ si ni ọpagun rẹ̀ lori mi.

5. Fi akara didùn da mi duro, fi eso igi tù mi ni inu: nitori aisàn ifẹ nṣe mi.

6. Ọwọ osì rẹ̀ mbẹ labẹ ori mi, ọwọ ọtún rẹ̀ si gbá mi mọra.

7. Mo fi awọn abo egbin, ati awọn abo agbọnrin igbẹ fi nyin bú, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, ki ẹ máṣe rú olufẹ mi soke, ki ẹ má si ṣe ji i, titi yio fi wù u.

8. Ohùn olufẹ mi! sa wò o, o mbọ̀, o nfò lori awọn òke, o mbẹ lori awọn òke kékeké.

9. Olufẹ mi dabi abo egbin, tabi ọmọ agbọnrin: sa wò o, o duro lẹhin ogiri wa, o yọju loju ferese, o nfi ara rẹ̀ hàn loju ferese ọlọnà.

10. Olufẹ mi sọ̀rọ, o si wi fun mi pe, Dide, olufẹ mi, arẹwà mi kanna, ki o si jade kalọ.

11. Sa wò o, ìgba otutu ti kọja, òjo ti da, o si ti lọ.

12. Awọn itanna eweko farahàn lori ilẹ; akoko ikọrin awọn ẹiyẹ de, a si gbọ ohùn àdaba ni ilẹ wa.

Ka pipe ipin O. Sol 2