Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Sol 1:8-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Bi iwọ kò ba mọ̀, Iwọ arẹwà julọ ninu awọn obinrin, jade lọ ni ipasẹ agbo-ẹran, ki iwọ ki o si bọ́ awọn ọmọ ewurẹ rẹ lẹba agọ awọn aluṣọ-agutan.

9. Olufẹ mi, mo ti fi ọ we ẹṣin mi ninu kẹkẹ́ Farao.

10. Ẹrẹkẹ́ rẹ li ẹwà ninu ọwọ́ ohun ọṣọ́, ọrùn rẹ ninu ilẹkẹ.

11. Awa o ṣe ọwọ́ ohun ọṣọ́ wura fun ọ, pẹlu ami fadaka.

12. Nigbati ọba wà ni ibujoko ijẹun rẹ̀, ororo mi rán õrun rẹ̀ jade.

Ka pipe ipin O. Sol 1