Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 98:4-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Ẹ ho iho ayọ̀ si Oluwa, gbogbo aiye: ẹ ho yè, ẹ yọ̀, ki ẹ si ma kọrin iyìn.

5. Ẹ ma fi duru kọrin si Oluwa, ati duru pẹlu ohùn orin-mimọ́.

6. Pẹlu ipè ati ohùn fere, ẹ ho iho ayọ̀ niwaju Oluwa, Ọba.

7. Jẹ ki okun ki o ma ho pẹlu ikún rẹ̀; aiye, ati awọn ti mbẹ ninu rẹ̀.

8. Jẹ ki odò ki o ma ṣapẹ, ki awọn òke ki o ma ṣe ajọyọ̀.

9. Niwaju Oluwa; nitori ti mbọwa iṣe idajọ aiye: pẹlu ododo ni yio fi ṣe idajọ aiye, ati awọn orilẹ-ède li aiṣègbe.

Ka pipe ipin O. Daf 98