Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 98:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ kọrin titun si Oluwa; nitoriti o ti ṣe ohun iyanu: ọwọ ọtún rẹ̀, ati apa rẹ̀ mimọ́ li o ti mu igbala wa fun ara rẹ̀.

2. Oluwa ti sọ igbala rẹ̀ di mimọ̀: ododo rẹ̀ li o ti fi hàn nigbangba li ojú awọn keferi.

3. O ti ranti ãnu rẹ̀ ati otitọ rẹ̀ si awọn ara ile Israeli: gbogbo opin aiye ti ri igbala Ọlọrun wa.

4. Ẹ ho iho ayọ̀ si Oluwa, gbogbo aiye: ẹ ho yè, ẹ yọ̀, ki ẹ si ma kọrin iyìn.

5. Ẹ ma fi duru kọrin si Oluwa, ati duru pẹlu ohùn orin-mimọ́.

Ka pipe ipin O. Daf 98