Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 94:13-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ki iwọ ki o le fun u ni isimi kuro li ọjọ ibi, titi a o fi wà iho silẹ fun enia buburu.

14. Nitoripe Oluwa kì yio ṣa awọn enia rẹ̀ tì, bẹ̃ni kì yio kọ̀ awọn enia-ini rẹ̀ silẹ.

15. Ṣugbọn idajọ yio pada si ododo: gbogbo ọlọkàn diduro ni yio si ma tọ̀ ọ lẹhin.

16. Tani yio dide si awọn oluṣe buburu fun mi? tabi tani yio dide si awọn oniṣẹ ẹ̀ṣe fun mi?

17. Bikoṣe bi Oluwa ti ṣe oluranlọwọ mi; ọkàn mi fẹrẹ joko ni idakẹ.

18. Nigbati mo wipe, Ẹsẹ mi yọ́; Oluwa, ãnu rẹ dì mi mu.

19. Ninu ọ̀pọlọpọ ibinujẹ mi ninu mi, itunu rẹ li o nmu inu mi dùn.

20. Itẹ́ ẹ̀ṣẹ ha le ba ọ kẹgbẹ pọ̀, ti nfi ofin dimọ ìwa-ika?

21. Nwọn kó ara wọn jọ pọ̀ si ọkàn olododo, nwọn si da ẹ̀jẹ alaiṣẹ lẹbi.

22. Ṣugbọn Oluwa li àbo mi; Ọlọrun mi si li apata àbo mi,

23. On o si mu ẹ̀ṣẹ wọn bọ̀ sori ara wọn, yio si ke wọn kuro ninu ìwa-buburu wọn: Oluwa Ọlọrun wa, yio ke wọn kuro.

Ka pipe ipin O. Daf 94