Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 92:6-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Ope enia kò mọ̀; bẹ̃li oye eyi kò ye aṣiwere enia.

7. Nigbati awọn enia buburu ba rú bi koriko, ati igbati gbogbo awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ ba ngberú: ki nwọn ki o le run lailai ni:

8. Ṣugbọn iwọ, Oluwa li ẹniti o ga titi lai.

9. Sa wò o, awọn ọta rẹ, Oluwa, sa wò o, awọn ọta rẹ yio ṣegbe; gbogbo oniṣẹ ẹ̀ṣẹ li a o tuka.

10. Ṣugbọn iwo mi ni iwọ o gbé ga bi iwo agbanrere; ororo titun li a o ta si mi lori.

11. Oju mi pẹlu yio ri ifẹ mi lara awọn ọta mi, eti mi yio si ma gbọ́ ifẹ mi si awọn enia buburu ti o dide si mi.

12. Olododo yio gbà bi igi ọpẹ: yio dàgba bi igi kedari Lebanoni.

13. Awọn ẹniti a gbin ni ile Oluwa, yio gbà ni agbala Ọlọrun wa.

14. Nwọn o ma so eso sibẹ ninu ogbó wọn: nwọn o sanra, nwọn o ma tutù nini;

15. Lati fi hàn pe, Ẹni diduro-ṣinṣin ni Oluwa: on li apata mi, kò si si aiṣododo kan ninu rẹ̀.

Ka pipe ipin O. Daf 92