10. Ṣugbọn iwo mi ni iwọ o gbé ga bi iwo agbanrere; ororo titun li a o ta si mi lori.
11. Oju mi pẹlu yio ri ifẹ mi lara awọn ọta mi, eti mi yio si ma gbọ́ ifẹ mi si awọn enia buburu ti o dide si mi.
12. Olododo yio gbà bi igi ọpẹ: yio dàgba bi igi kedari Lebanoni.
13. Awọn ẹniti a gbin ni ile Oluwa, yio gbà ni agbala Ọlọrun wa.
14. Nwọn o ma so eso sibẹ ninu ogbó wọn: nwọn o sanra, nwọn o ma tutù nini;
15. Lati fi hàn pe, Ẹni diduro-ṣinṣin ni Oluwa: on li apata mi, kò si si aiṣododo kan ninu rẹ̀.