1. OHUN rere ni lati ma fi ọpẹ fun Oluwa, ati lati ma kọrin si orukọ rẹ, Ọga-ogo:
2. Lati ma fi iṣeun ifẹ rẹ hàn li owurọ, ati otitọ rẹ li alalẹ.
3. Lara ohun-elo orin olokùn mẹwa, ati lara ohun-elo orin mimọ́: lara duru pẹlu iró ti o ni ironu.
4. Nitori iwọ, Oluwa, li o ti mu mi yọ̀ nipa iṣẹ rẹ: emi o ma kọrin iyìn nitori iṣẹ ọwọ rẹ.