Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 91:3-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Nitõtọ on o gbà ọ ninu ikẹkun awọn pẹyẹpẹyẹ, ati ninu àjakalẹ-àrun buburu.

4. Yio fi iyẹ́ rẹ̀ bò ọ, abẹ iyẹ́-apa rẹ̀ ni iwọ o si gbẹkẹle: otitọ rẹ̀ ni yio ṣe asà ati apata rẹ.

5. Iwọ kì yio bẹ̀ru nitori ẹ̀ru oru; tabi fun ọfa ti nfo li ọsán;

6. Tabi fun àjakalẹ-àrun ti nrìn kiri li okunkun, tabi fun iparun ti nrun-ni li ọsángangan.

7. Ẹgbẹrun yio ṣubu li ẹgbẹ rẹ, ati ẹgbarun li apa ọtún rẹ: ṣugbọn kì yio sunmọ ọdọ rẹ.

8. Kiki oju rẹ ni iwọ o ma fi ri, ti o si ma fi wo ère awọn enia buburu.

9. Nitori iwọ, Oluwa, ni iṣe ãbo mi, iwọ ti fi Ọga-ogo ṣe ibugbe rẹ.

10. Buburu kan kì yio ṣubu lu ọ, bẹ̃li arunkarun kì yio sunmọ ile rẹ.

Ka pipe ipin O. Daf 91