Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 90:6-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Ni Kutukutu o li àwọ lara, o si dàgba soke, li asalẹ a ké e lulẹ, o si rọ.

7. Nitori awa di egbé nipa ibinu rẹ, ati nipa ibinu rẹ ara kò rọ̀ wa.

8. Iwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ wa ka iwaju rẹ, ohun ìkọkọ wa mbẹ ninu imọlẹ iwaju rẹ.

9. Nitori ọjọ wa gbogbo nyipo lọ ninu ibinu rẹ: awa nlo ọjọ wa bi alá ti a nrọ́.

10. Adọrin ọdun ni iye ọjọ ọdun wa; bi o si ṣepe nipa ti agbara, bi nwọn ba to ọgọrin ọdun, agbara wọn lãla on ibinujẹ ni; nitori pe a kì o pẹ ke e kuro, awa a si fò lọ.

11. Tali o mọ̀ agbara ibinu rẹ? gẹgẹ bi ẹ̀ru rẹ, bẹ̃ni ibinu rẹ.

12. Bẹ̃ni ki iwọ ki o kọ́ wa lati ma ka iye ọjọ wa, ki awa ki o le fi ọkàn wa sipa ọgbọ́n.

13. Pada, Oluwa, yio ti pẹ to? yi ọkàn pada nitori awọn ọmọ-ọdọ rẹ.

14. Fi ãnu rẹ tẹ́ wa li ọrùn ni kutukutu; ki awa ki o le ma yọ̀, ati ki inu wa ki o le ma dùn li ọjọ wa gbogbo.

Ka pipe ipin O. Daf 90