Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 90:12-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Bẹ̃ni ki iwọ ki o kọ́ wa lati ma ka iye ọjọ wa, ki awa ki o le fi ọkàn wa sipa ọgbọ́n.

13. Pada, Oluwa, yio ti pẹ to? yi ọkàn pada nitori awọn ọmọ-ọdọ rẹ.

14. Fi ãnu rẹ tẹ́ wa li ọrùn ni kutukutu; ki awa ki o le ma yọ̀, ati ki inu wa ki o le ma dùn li ọjọ wa gbogbo.

15. Mu inu wa dùn bi iye ọjọ ti iwọ pọ́n wa loju, ati iye ọdun ti awa ti nri buburu.

16. Jẹ ki iṣẹ rẹ ki o hàn si awọn ọmọ-ọ̀dọ rẹ, ati ogo rẹ si awọn ọmọ wọn.

17. Jẹ ki ẹwà Oluwa Ọlọrun wa ki o wà lara wa: ki iwọ ki o si fi idi iṣẹ ọwọ wa mulẹ lara wa, bẹ̃ni iṣẹ ọwọ wa ni ki iwọ ki o fi idi rẹ̀ mulẹ.

Ka pipe ipin O. Daf 90