Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 90:11-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Tali o mọ̀ agbara ibinu rẹ? gẹgẹ bi ẹ̀ru rẹ, bẹ̃ni ibinu rẹ.

12. Bẹ̃ni ki iwọ ki o kọ́ wa lati ma ka iye ọjọ wa, ki awa ki o le fi ọkàn wa sipa ọgbọ́n.

13. Pada, Oluwa, yio ti pẹ to? yi ọkàn pada nitori awọn ọmọ-ọdọ rẹ.

14. Fi ãnu rẹ tẹ́ wa li ọrùn ni kutukutu; ki awa ki o le ma yọ̀, ati ki inu wa ki o le ma dùn li ọjọ wa gbogbo.

15. Mu inu wa dùn bi iye ọjọ ti iwọ pọ́n wa loju, ati iye ọdun ti awa ti nri buburu.

Ka pipe ipin O. Daf 90