Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 9:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EMI o fi gbogbo aiya mi yìn Oluwa: emi o fi gbogbo iṣẹ iyanu rẹ hàn.

2. Emi o yọ̀, emi o si ṣe inu-didùn ninu rẹ, emi o si kọrin iyìn si orukọ rẹ, iwọ Ọga-ogo julọ.

3. Nigbati awọn ọta mi ba pẹhinda, nwọn o ṣubu, nwọn o si ṣegbe ni iwaju rẹ.

4. Nitori iwọ li o ti mu idajọ mi ati idi ọ̀ran mi duro; iwọ li o joko lori itẹ́, ti o nṣe idajọ ododo.

5. Iwọ ba awọn orilẹ-ède wi, iwọ pa awọn enia buburu run, iwọ pa orukọ wọn rẹ́ lai ati lailai.

6. Niti ọta, iparun wọn pari tan lailai: iwọ li o si ti run ilu wọnni; iranti wọn si ti ṣegbe pẹlu wọn.

7. Ṣugbọn Oluwa yio wà titi lailai: o ti tẹ́ itẹ́ rẹ̀ silẹ fun idajọ.

8. On o si ṣe idajọ aiye li ododo, yio ṣe idajọ fun awọn enia li otitọ ìwa.

Ka pipe ipin O. Daf 9