45. Ọjọ ewe rẹ̀ ni iwọ ke kuru; iwọ fi itìju bò o.
46. Yio ti pẹ to, Oluwa? iwọ o pa ara rẹ mọ́ lailai? ibinu rẹ yio ha jo bi iná bi?
47. Ranti bi ọjọ mi ti kuru to; ẽse ti iwọ ha da gbogbo enia lasan?
48. Ọkunrin wo li o wà lãye, ti kì yio ri ikú? ti yio gbà ọkàn rẹ̀ lọwọ isa-okú.
49. Oluwa, nibo ni iṣeun-ifẹ rẹ atijọ wà, ti iwọ bura fun Dafidi ninu otitọ rẹ?
50. Oluwa, ranti ẹ̀gan awọn iranṣẹ rẹ, ti emi nrù li aiya mi lati ọdọ gbogbo ọ̀pọ enia.