Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 89:41-48 Yorùbá Bibeli (YCE)

41. Gbogbo awọn ti nkọja lọ li ọ̀na nfi ṣe ijẹ: on si di ẹ̀gan fun awọn aladugbo rẹ̀.

42. Iwọ ti gbé ọwọ ọtún awọn ọta rẹ̀ soke; iwọ mu gbogbo awọn ọta rẹ̀ yọ̀.

43. Iwọ si ti yi oju idà rẹ̀ pada pẹlu, iwọ kò si mu u duro li oju ogun.

44. Iwọ ti mu ogo rẹ̀ tẹ́, iwọ si wọ́ itẹ́ rẹ̀ silẹ-yilẹ.

45. Ọjọ ewe rẹ̀ ni iwọ ke kuru; iwọ fi itìju bò o.

46. Yio ti pẹ to, Oluwa? iwọ o pa ara rẹ mọ́ lailai? ibinu rẹ yio ha jo bi iná bi?

47. Ranti bi ọjọ mi ti kuru to; ẽse ti iwọ ha da gbogbo enia lasan?

48. Ọkunrin wo li o wà lãye, ti kì yio ri ikú? ti yio gbà ọkàn rẹ̀ lọwọ isa-okú.

Ka pipe ipin O. Daf 89