28. Ãnu mi li emi o pamọ́ fun u lailai, ati majẹmu mi yio si ba a duro ṣinṣin.
29. Irú-ọmọ rẹ̀ pẹlu li emi o mu pẹ titi, ati itẹ́ rẹ̀ bi ọjọ ọrun.
30. Bi awọn ọmọ rẹ̀ ba kọ̀ ofin mi silẹ, ti nwọn kò si rìn nipa idajọ mi;
31. Bi nwọn ba bá ilana mi jẹ, ti nwọn kò si pa ofin mi mọ́,
32. Nigbana li emi o fi ọgọ bẹ irekọja wọn wò, ati ẹ̀ṣẹ wọn pẹlu ìna.
33. Ṣugbọn iṣeun-ifẹ mi li emi kì yio gbà lọwọ rẹ̀, bẹ̃li emi kì yio jẹ ki otitọ mi ki o yẹ̀.
34. Majẹmu mi li emi kì yio dà, bẹ̃li emi kì yio yi ohun ti o ti ète mi jade pada.
35. Lẹrinkan ni mo ti fi ìwa-mimọ́ mi bura pe, emi kì yio purọ fun Dafidi.
36. Iru-ọmọ rẹ̀ yio duro titi lailai, ati itẹ́ rẹ̀ bi õrun niwaju mi.
37. A o fi idi rẹ̀ mulẹ lailai bi òṣupa, ati bi ẹlẹri otitọ li ọrun.