11. Ọrun ni tirẹ, aiye pẹlu ni tirẹ: aiye ati ẹ̀kun rẹ̀, iwọ li o ti ṣe ipilẹ wọn.
12. Ariwa ati gusù iwọ li o ti da wọn: Taboru ati Hermoni yio ma yọ̀ li orukọ rẹ.
13. Iwọ ni apá agbara: agbara li ọwọ́ rẹ, giga li ọwọ ọtún rẹ.
14. Otitọ ati idajọ ni ibujoko itẹ́ rẹ: ãnu ati otitọ ni yio ma lọ siwaju rẹ.
15. Ibukún ni fun awọn enia ti o mọ̀ ohùn ayọ̀ nì: Oluwa, nwọn o ma rìn ni imọlẹ oju rẹ.
16. Li orukọ rẹ ni nwọn o ma yọ̀ li ọjọ gbogbo: ati ninu ododo rẹ li a o ma gbé wọn leke.
17. Nitori iwọ li ogo agbara wọn: ati ninu ore ojurere rẹ li a o gbé iwo wa soke,
18. Nitori Oluwa li asà wa: Ẹni-Mimọ́ Israeli li ọba wa.
19. Nigbana ni iwọ sọ li oju iran fun ayanfẹ rẹ, o si wipe, Emi ti gbé iranlọwọ ru ẹni-alagbara; emi ti gbé ẹnikan leke ti a yàn ninu awọn enia.
20. Emi ti ri Dafidi, iranṣẹ mi; ororo mi mimọ́ ni mo ta si i li ori:
21. Nipasẹ ẹniti a o fi ọwọ mi mulẹ: apá mi pẹlu yio ma mu u li ara le.