Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 86:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA, dẹ eti rẹ silẹ, gbohùn mi: nitori ti emi jẹ́ talaka ati alaini.

2. Pa ọkàn mi mọ́; nitori emi li ẹniti iwọ ṣe ojurere fun: iwọ, Ọlọrun mi, gbà ọmọ ọdọ rẹ ti o gbẹkẹle ọ.

3. Ṣãnu fun mi, Oluwa: nitori iwọ li emi nkepè lojojumọ.

4. Mu ọkàn iranṣẹ rẹ yọ̀: Oluwa, nitori iwọ ni mo gbé ọkàn mi soke si.

5. Nitori iwọ, Oluwa, o ṣeun, o si mura ati dariji; o si pọ̀ li ãnu fun gbogbo awọn ti nkepè ọ.

6. Oluwa, fi eti si adura mi; ki o si fiye si ohùn ẹ̀bẹ mi.

7. Li ọjọ ipọnju mi, emi o kepè ọ: nitori ti iwọ o da mi lohùn.

8. Oluwa, ninu awọn oriṣa kò si ọ̀kan ti o dabi rẹ, bẹ̃ni kò si iṣẹ kan ti o dabi iṣẹ rẹ.

9. Gbogbo awọn orilẹ-ède ti iwọ da ni yio wá, nwọn o si sìn niwaju rẹ, Oluwa; nwọn o si ma fi ogo fun orukọ rẹ.

10. Nitoripe iwọ pọ̀, iwọ si nṣe ohun iyanu: iwọ nikan li Ọlọrun.

Ka pipe ipin O. Daf 86