Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 84:9-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Kiyesi i, Ọlọrun asà wa, ki o si ṣiju wò oju Ẹni-ororo rẹ.

10. Nitori pe ọjọ kan ninu agbala rẹ sanju ẹgbẹrun ọjọ lọ. Mo fẹ ki nkuku ma ṣe adena ni ile Ọlọrun mi, jù lati ma gbe agọ ìwa-buburu.

11. Nitori Oluwa Ọlọrun li õrun ati asà: Oluwa yio fun ni li ore-ọfẹ ati ogo: kò si ohun rere ti yio fà sẹhin lọwọ awọn ti nrìn dede.

12. Oluwa awọn ọmọ-ogun, ibukún ni fun oluwarẹ̀ na ti o gbẹkẹle ọ.

Ka pipe ipin O. Daf 84