Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 81:6-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Mo gbé ejika rẹ̀ kuro ninu ẹrù: mo si gbà agbọn li ọwọ rẹ̀.

7. Iwọ pè ninu ipọnju, emi si gbà ọ; emi da ọ lohùn nibi ìkọkọ ãra: emi ridi rẹ nibi omi ija.

8. Ẹ gbọ́, ẹnyin enia mi, emi o si jẹri si ọ: Israeli, bi iwọ ba fetisi mi.

9. Kì yio si ọlọrun miran ninu nyin; bẹ̃ni iwọ kì yio sìn ọlọrun àjeji.

10. Emi ni Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o mu ọ lati ilẹ Egipti jade wá: yà ẹ̀nu rẹ̀ gbòro, emi o si kún u.

11. Ṣugbọn awọn enia mi kò fẹ igbọ́ ohùn mi; Israeli kò si fẹ ti emi.

12. Bẹ̃ni mo fi wọn silẹ fun lile aiya wọn: nwọn si nrìn ninu ero ara wọn.

13. Ibaṣepe awọn enia mi ti gbọ́ ti emi, ati ki Israeli ki o ma rìn nipa ọ̀na mi!

14. Emi iba ti ṣẹ́ awọn ọta wọn lọgan, emi iba si ti yi ọwọ mi pada si awọn ọta wọn.

15. Awọn akorira Oluwa iba ti fi ori wọn balẹ fun u; igba wọn iba si duro pẹ titi.

16. Alikama daradara ni on iba ma fi bọ́ wọn pẹlu: ati oyin inu apata ni emi iba si ma fi tẹ́ ọ lọrun.

Ka pipe ipin O. Daf 81