Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 81:2-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ẹ mu orin mimọ́, ki ẹ si mu ìlu wa, duru didùn pẹlu ohun-elo orin mimọ́.

3. Ẹ fun ipè li oṣù titún, ni ìgbà ti a lana silẹ, li ọjọ ajọ wa ti o ni ironu.

4. Nitori eyi li aṣẹ fun Israeli, ati ofin Ọlọrun Jakobu.

5. Eyi li o dasilẹ ni ẹrí fun Josefu, nigbati o là ilẹ Egipti ja; nibiti mo gbe gbọ́ ede ti kò ye mi.

6. Mo gbé ejika rẹ̀ kuro ninu ẹrù: mo si gbà agbọn li ọwọ rẹ̀.

7. Iwọ pè ninu ipọnju, emi si gbà ọ; emi da ọ lohùn nibi ìkọkọ ãra: emi ridi rẹ nibi omi ija.

8. Ẹ gbọ́, ẹnyin enia mi, emi o si jẹri si ọ: Israeli, bi iwọ ba fetisi mi.

9. Kì yio si ọlọrun miran ninu nyin; bẹ̃ni iwọ kì yio sìn ọlọrun àjeji.

10. Emi ni Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o mu ọ lati ilẹ Egipti jade wá: yà ẹ̀nu rẹ̀ gbòro, emi o si kún u.

11. Ṣugbọn awọn enia mi kò fẹ igbọ́ ohùn mi; Israeli kò si fẹ ti emi.

12. Bẹ̃ni mo fi wọn silẹ fun lile aiya wọn: nwọn si nrìn ninu ero ara wọn.

Ka pipe ipin O. Daf 81