Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 80:11-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. O yọ ẹka rẹ̀ sinu okun, ati ọwọ rẹ̀ si odò nla nì.

12. Ẽṣe ti iwọ ha fi ya ọgbà rẹ̀ bẹ̃, ti gbogbo awọn ẹniti nkọja lọ li ọ̀na nká a?

13. Imado lati inu igbo wá mba a jẹ, ati ẹranko igbẹ njẹ ẹ run.

14. Yipada, awa mbẹ ọ, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun: wolẹ lati ọrun wá, ki o si wò o, ki o si bẹ àjara yi wò:

15. Ati agbala-àjara ti ọwọ ọtún rẹ ti gbin, ati ọmọ ti iwọ ti mule fun ara rẹ.

16. O jona, a ke e lulẹ: nwọn ṣegbe nipa ibawi oju rẹ.

17. Jẹ ki ọwọ rẹ ki o wà lara ọkunrin ọwọ ọtún rẹ nì, lara ọmọ-enia ti iwọ ti mule fun ara rẹ.

18. Bẹ̃li awa kì yio pada sẹhin kuro lọdọ rẹ: mu wa yè, awa o si ma pè orukọ rẹ.

19. Tún wa yipada, Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, mu oju rẹ tàn imọlẹ; a o si gbà wa là.

Ka pipe ipin O. Daf 80