Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 80:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. FI eti si ni, Oluṣọ-agutan Israeli, iwọ ti o ndà Josefu bi ọwọ́-agutan; iwọ ti o joko lãrin awọn kerubu tàn imọlẹ jade.

2. Niwaju Efraimu ati Benjamini ati Manasse rú ipa rẹ soke ki o si wá fun igbala wa.

3. Tún wa yipada, Ọlọrun, ki o si mu oju rẹ tàn imọlẹ; a o si gbà wa là.

4. Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, iwọ o ti binu pẹ to si adura awọn enia rẹ?

5. Iwọ fi onjẹ omije bọ́ wọn; iwọ si fun wọn li omije mu li ọ̀pọlọpọ.

6. Iwọ sọ wa di ijà fun awọn aladugbo wa: awọn ọta wa si nrẹrin ninu ara wọn.

7. Tún wa yipada, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ki o si mu oju rẹ tàn imọlẹ; a o si gbà wa là.

8. Iwọ ti mu ajara kan jade ti Egipti wá: iwọ ti tì awọn keferi jade, iwọ si gbin i.

9. Iwọ ṣe àye silẹ fun u, iwọ si mu u ta gbòngbo jinlẹ̀, o si kún ilẹ na.

10. A fi ojiji rẹ̀ bò awọn òke mọlẹ, ati ẹka rẹ̀ dabi igi kedari Ọlọrun.

Ka pipe ipin O. Daf 80