Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 79:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ỌLỌRUN, awọn keferi wá si ilẹ-ini rẹ; tempili mimọ́ rẹ ni nwọn sọ di ẽri; nwọn sọ Jerusalemu di òkiti-alapa.

2. Okú awọn iranṣẹ rẹ ni nwọn fi fun ẹiyẹ oju-ọrun li onjẹ, ẹran-ara awọn enia mimọ́ rẹ fun ẹranko ilẹ.

3. Ẹ̀jẹ wọn ni nwọn ta silẹ bi omi yi Jerusalemu ka; kò si si ẹniti yio gbé wọn sìn.

4. Awa di ẹ̀gan si awọn aladugbo wa, ẹlẹya ati iyọṣuti si awọn ti o yi wa ka.

5. Yio ti pẹ to, Oluwa? iwọ o binu titi lailai? owú rẹ yio ha ma jó bi iná?

6. Dà ibinu rẹ si ori awọn keferi ti kò mọ̀ ọ, ati si ori awọn ijọba ti kò kepè orukọ rẹ.

7. Nitori ti nwọn ti mu Jakobu jẹ, nwọn si sọ ibujoko rẹ̀ di ahoro.

8. Máṣe ranti ẹ̀ṣẹ awọn aṣaju wa si wa: jẹ ki iyọnu rẹ ki o ṣaju wa nisisiyi: nitori ti a rẹ̀ wa silẹ gidigidi.

Ka pipe ipin O. Daf 79