Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 78:57-69 Yorùbá Bibeli (YCE)

57. Ṣugbọn nwọn yipada, nwọn ṣe alaiṣotitọ bi awọn baba wọn: nwọn si pẹhinda si apakan bi ọrun ẹ̀tan.

58. Nitori ti nwọn fi ibi giga wọn bi i ninu, nwọn si fi ere finfin wọn mu u jowu.

59. Nigbati Ọlọrun gbọ́ eyi, o binu, o si korira Israeli gidigidi.

60. Bẹ̃li o kọ̀ agọ Ṣilo silẹ, agọ ti o pa ninu awọn enia.

61. O si fi agbara rẹ̀ fun igbekun, ati ogo rẹ̀ le ọwọ ọta nì.

62. O fi awọn enia rẹ̀ fun idà pẹlu; o si binu si ilẹ-ini rẹ̀.

63. Iná run awọn ọdọmọkunrin wọn; a kò si fi orin sin awọn wundia wọn ni iyawo.

64. Awọn alufa wọn ti oju idà ṣubu; awọn opó wọn kò si pohunrere ẹkún.

65. Nigbana li Oluwa ji bi ẹnipe loju orun, ati bi alagbara ti o nkọ nitori ọti-waini.

66. O si kọlu awọn ọta rẹ̀ lẹhin; o sọ wọn di ẹ̀gan titi aiye.

67. Pẹlupẹlu o kọ̀ agọ Josefu, kò si yàn ẹ̀ya Efraimu:

68. Ṣugbọn o yan ẹ̀ya Juda, òke Sioni ti o fẹ.

69. O si kọ́ ibi-mimọ́ rẹ̀ bi òke-ọrun bi ilẹ ti o ti fi idi rẹ̀ mulẹ lailai.

Ka pipe ipin O. Daf 78