Ṣugbọn on, o kún fun iyọ́nu, o fi ẹ̀ṣẹ wọn jì wọn, kò si run wọn: nitõtọ, nigba pupọ̀ li o yi ibinu rẹ̀ pada, ti kò si ru gbogbo ibinu rẹ̀ soke.