Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 78:3-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Ti awa ti gbọ́, ti a si ti mọ̀, ti awọn baba wa si ti sọ fun wa.

4. Awa kì yio pa wọn mọ́ kuro lọdọ awọn ọmọ wọn, ni fifi iyìn Oluwa, ati ipa rẹ̀, ati iṣẹ iyanu ti o ti ṣe hàn fun iran ti mbọ.

5. Nitori ti o gbé ẹri kalẹ ni Jakobu, o si sọ ofin kan ni Israeli, ti o ti pa li aṣẹ fun awọn baba wa pe, ki nwọn ki o le sọ wọn di mimọ̀ fun awọn ọmọ wọn.

6. Ki awọn iran ti mbọ̀ ki o le mọ̀, ani awọn ọmọ ti a o bi: ti yio si dide, ti yio si sọ fun awọn ọmọ wọn:

7. Ki nwọn ki o le ma gbé ireti wọn le Ọlọrun, ki nwọn ki o má si ṣe gbagbe iṣẹ Ọlọrun, ṣugbọn ki nwọn ki o pa ofin rẹ̀ mọ́.

8. Ki nwọn ki o máṣe dabi awọn baba wọn, iran alagidi ati ọlọ̀tẹ̀; iran ti kò fi ọkàn wọn le otitọ, ati ẹmi ẹniti kò ba Ọlọrun duro ṣinṣin.

9. Awọn ọmọ Efraimu ti o hamọra ogun, ti nwọn mu ọrun, nwọn yipada li ọjọ ogun.

10. Nwọn kò pa majẹmu Ọlọrun mọ́, nwọn si kọ̀ lati ma rìn ninu ofin rẹ̀.

Ka pipe ipin O. Daf 78