Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 75:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ỌLỌRUN, iwọ li awa fi ọpẹ fun, iwọ li awa fi ọpẹ fun nitori orukọ rẹ sunmọ itosi, iṣẹ iyanu rẹ fi hàn.

2. Nigbati akokò mi ba de, emi o fi otitọ ṣe idajọ.

3. Aiye ati gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀ warìri: emi li o rù ọwọ̀n rẹ̀.

4. Emi wi fun awọn agberaga pe, Ẹ máṣe gbéraga mọ́: ati fun awọn enia buburu pe, Ẹ máṣe gbé iwo nì soke.

5. Ẹ máṣe gbé iwo nyin ga: ẹ máṣe fi ọrùn lile sọ̀rọ.

6. Nitori ti igbega kò ti ìla-õrùn wá, tabi ni ìwọ-õrùn, bẹ̃ni kì iṣe lati gusu wá.

7. Ṣugbọn Ọlọrun li onidajọ: o sọ ọkan kalẹ, o gbé ẹlomiran leke.

8. Nitoripe li ọwọ Oluwa li ago kan wà, ọti-waini na si pọ́n: o kún fun àdalu: o si dà jade ninu rẹ̀; ṣugbọn gèdẹgẹdẹ rẹ̀, gbogbo awọn enia buburu aiye ni yio fun u li afun-mu.

9. Ṣugbọn emi o ma sọ titi lai, emi o ma kọrin iyìn si Ọlọrun Jakobu.

10. Gbogbo iwo awọn enia buburu li emi o ke kuro; ṣugbọn iwo awọn olododo li emi o gbé soke.

Ka pipe ipin O. Daf 75