Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 74:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ỌLỌRUN, ẽṣe ti iwọ fi ta wa nù titi lai! ẽṣe ti ibinu rẹ fi nrú si agutan papa rẹ?

2. Ranti ijọ enia rẹ ti iwọ ti rà nigba atijọ; ilẹ-ini rẹ ti iwọ ti rà pada; òke Sioni yi, ninu eyi ti iwọ ngbe.

3. Gbé ẹsẹ rẹ soke si ahoro lailai nì; ani si gbogbo eyiti ọta ti fi buburu ṣe ni ibi-mimọ́.

4. Awọn ọta rẹ nke ramu-ramu lãrin ijọ enia rẹ; nwọn gbé asia wọn soke fun àmi.

5. Nwọn dabi ọkunrin ti ngbé akeke rẹ̀ soke ninu igbo didi,

6. Ṣugbọn nisisiyi iṣẹ ọnà finfin ni nwọn fi akeke ati òlu wó lulẹ pọ̀ li ẹ̃kan.

7. Nwọn tinabọ ibi-mimọ́ rẹ, ni wiwo ibujoko orukọ rẹ lulẹ, nwọn sọ ọ di ẽri.

8. Nwọn wi li ọkàn wọn pe, Ẹ jẹ ki a run wọn pọ̀: nwọn ti kun gbogbo ile Ọlọrun ni ilẹ na.

Ka pipe ipin O. Daf 74