Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 73:1-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NITÕTỌ Ọlọrun ṣeun fun Israeli, fun iru awọn ti iṣe alaiya mimọ́.

2. Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, ẹsẹ mi fẹrẹ yẹ̀ tan; ìrin mi fẹrẹ yọ́ tan.

3. Nitori ti emi ṣe ilara si awọn aṣe-fefe, nigbati mo ri alafia awọn enia buburu.

4. Nitoriti kò si irora ninu ikú wọn: agbara wọn si pọ̀.

5. Nwọn kò ni ipin ninu iyọnu enia; bẹ̃ni a kò si wahala wọn pẹlu ẹlomiran.

6. Nitorina ni igberaga ṣe ká wọn lọrun bi ẹ̀wọn ọṣọ́; ìwa-ipa bò wọn mọlẹ bi aṣọ.

7. Oju wọn yọ jade fun isanra: nwọn ní jù bi ọkàn wọn ti nfẹ lọ.

8. Nwọn nṣẹsin, nwọn si nsọ̀rọ buburu niti inilara: nwọn nsọ̀rọ lati ibi giga.

9. Nwọn gbé ẹnu wọn le ọrun, ahọn wọn si nrìn ilẹ já.

10. Nitorina li awọn enia rẹ̀ ṣe yipada si ihin: ọ̀pọlọpọ omi li a si npọn jade fun wọn.

11. Nwọn si wipe, Ọlọrun ti ṣe mọ̀? ìmọ ha wà ninu Ọga-ogo?

12. Kiyesi i, awọn wọnyi li alaìwa-bi-ọlọrun, ẹniti aiye nsan, nwọn npọ̀ li ọrọ̀.

13. Nitõtọ li asan ni mo wẹ̀ aiya mi mọ́, ti mo si wẹ̀ ọwọ mi li ailẹ̀ṣẹ.

14. Nitoripe ni gbogbo ọjọ li a nyọ mi lẹnu, a si nnà mi li orowurọ.

Ka pipe ipin O. Daf 73