Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 72:10-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Awọn ọba Tarṣiṣi, ati ti awọn erekuṣu yio mu ọrẹ wá: awọn ọba Ṣeba ati ti Seba yio mu ẹ̀bun wá.

11. Nitõtọ, gbogbo awọn ọba ni yio wolẹ niwaju rẹ̀: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio ma sìn i.

12. Nitori yio gbà alaini nigbati o ba nke: talaka pẹlu, ati ẹniti kò li oluranlọwọ.

13. On o da talaka ati alaini si, yio si gbà ọkàn awọn alaini là.

14. On o rà ọkàn wọn pada lọwọ ẹ̀tan ati ìwa-agbara: iyebiye si li ẹ̀jẹ wọn li oju rẹ̀.

15. On o si yè, on li a o si fi wura Ṣeba fun: a o si ma gbadura fun u nigbagbogbo: lojojumọ li a o si ma yìn i.

Ka pipe ipin O. Daf 72