Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 72:1-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ỌLỌRUN, fi idajọ rẹ fun ọba, ati ododo rẹ fun ọmọ ọba.

2. On o ma fi ododo ṣe idajọ awọn enia rẹ, yio si ma fi ẹtọ́ ṣe idajọ awọn talaka rẹ.

3. Awọn òke nla yio ma mu alafia fun awọn enia wá, ati awọn òke kekeke nipa ododo.

4. On o ma ṣe idajọ awọn talaka enia, yio ma gbà awọn ọmọ awọn alaini, yio si fà aninilara ya pẹrẹ-pẹrẹ.

5. Nwọn o si ma bẹ̀ru rẹ, niwọ̀n bi õrùn ati oṣupa yio ti pẹ to, lati irandiran.

6. On o rọ̀ si ilẹ bi ojò si ori koriko itẹ̀mọlẹ: bi ọwọ òjo ti o rin ilẹ.

7. Li ọjọ rẹ̀ li awọn olododo yio gbilẹ: ati ọ̀pọlopọ alafia niwọn bi òṣupa yio ti pẹ to.

8. On o si jọba lati okun de okun, ati lati odò nì de opin aiye.

9. Awọn ti o joko li aginju yio tẹriba fun u; awọn ọta rẹ̀ yio si lá erupẹ ilẹ.

10. Awọn ọba Tarṣiṣi, ati ti awọn erekuṣu yio mu ọrẹ wá: awọn ọba Ṣeba ati ti Seba yio mu ẹ̀bun wá.

11. Nitõtọ, gbogbo awọn ọba ni yio wolẹ niwaju rẹ̀: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio ma sìn i.

12. Nitori yio gbà alaini nigbati o ba nke: talaka pẹlu, ati ẹniti kò li oluranlọwọ.

13. On o da talaka ati alaini si, yio si gbà ọkàn awọn alaini là.

14. On o rà ọkàn wọn pada lọwọ ẹ̀tan ati ìwa-agbara: iyebiye si li ẹ̀jẹ wọn li oju rẹ̀.

Ka pipe ipin O. Daf 72