Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 7:7-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Bẹ̃ni ijọ awọn enia yio yi ọ ká kiri; njẹ nitori wọn iwọ pada si òke.

8. Oluwa yio ṣe idajọ awọn enia: Oluwa ṣe idajọ mi, gẹgẹ bi ododo mi, ati gẹgẹ bi ìwatitọ inu mi.

9. Jẹ ki ìwa-buburu awọn enia buburu ki o de opin: ṣugbọn mu olotitọ duro: nitoriti Ọlọrun olododo li o ndan aiya ati inu wò.

10. Abo mi mbẹ lọdọ Ọlọrun ti o nṣe igbala olotitọ li aiya.

11. Ọlọrun li onidajọ ododo, Ọlọrun si nbinu si enia buburu lojojumọ:

12. Bi on kò ba yipada, yio si pọ́n idà rẹ̀ mu: o ti fà ọrun rẹ̀ le na, o ti mura rẹ̀ silẹ.

13. O si ti pèse elo ikú silẹ fun u; o ti ṣe awọn ọfa rẹ̀ ni oniná.

14. Kiyesi i, o nrọbi ẹ̀ṣẹ, o si loyun ìwa-ìka, o si bí eké jade.

15. O ti wà ọ̀fin, o gbẹ́ ẹ, o si bọ́ sinu iho ti on na wà.

16. Ìwa-ika rẹ̀ yio si pada si ori ara rẹ̀, ati ìwa-agbara rẹ̀ yio si sọ̀kalẹ bọ̀ si atari ara rẹ̀.

17. Emi o yìn Oluwa gẹgẹ bi ododo rẹ̀: emi o si kọrin iyìn si orukọ Oluwa Ọga-ogo julọ.

Ka pipe ipin O. Daf 7