Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 7:4-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Bi mo ba fi ibi san a fun ẹniti temi tirẹ̀ wà li alafia; (nitõtọ ẹniti nṣe ọta mi li ainidi, emi tilẹ gbà a là:)

5. Jẹ ki ọta ki o ṣe inunibini si ọkàn mi, ki o si mu u; ki o tẹ̀ ẹmi mi mọlẹ, ki o si fi ọlá mi le inu ekuru.

6. Dide Oluwa, ni ibinu rẹ! gbé ara rẹ soke nitori ikannu awọn ọta mi: ki iwọ ki o si jí fun mi si idajọ ti iwọ ti pa li aṣẹ.

7. Bẹ̃ni ijọ awọn enia yio yi ọ ká kiri; njẹ nitori wọn iwọ pada si òke.

8. Oluwa yio ṣe idajọ awọn enia: Oluwa ṣe idajọ mi, gẹgẹ bi ododo mi, ati gẹgẹ bi ìwatitọ inu mi.

9. Jẹ ki ìwa-buburu awọn enia buburu ki o de opin: ṣugbọn mu olotitọ duro: nitoriti Ọlọrun olododo li o ndan aiya ati inu wò.

10. Abo mi mbẹ lọdọ Ọlọrun ti o nṣe igbala olotitọ li aiya.

11. Ọlọrun li onidajọ ododo, Ọlọrun si nbinu si enia buburu lojojumọ:

12. Bi on kò ba yipada, yio si pọ́n idà rẹ̀ mu: o ti fà ọrun rẹ̀ le na, o ti mura rẹ̀ silẹ.

Ka pipe ipin O. Daf 7