20. Ẹgan ti bà mi ni inu jẹ; emi si kún fun ikãnu: emi si woye fun ẹniti yio ṣãnu fun mi, ṣugbọn kò si; ati fun awọn olutunu, emi kò si ri ẹnikan.
21. Nwọn fi orõro fun mi pẹlu li ohun jijẹ mi; ati li ongbẹ mi nwọn fun mi li ọti kikan ni mimu.
22. Jẹ ki tabili wọn ki o di ikẹkun niwaju wọn: fun awọn ti o wà li alafia, ki o si di okùn didẹ.
23. Jẹ ki oju wọn ki o ṣú, ki nwọn ki o má riran, ki o si ma mu ẹgbẹ́ wọn gbọn nigbagbogbo.
24. Dà irunu rẹ si wọn lori, si jẹ ki ikannu ibinu rẹ ki o le wọn ba.
25. Jẹ ki ibujoko wọn ki o di ahoro; ki ẹnikẹni ki o máṣe gbe inu agọ wọn.
26. Nitori ti nwọn nṣe inunibini si ẹniti iwọ ti lù; nwọn si nsọ̀rọ ibinujẹ ti awọn ti iwọ ti ṣá li ọgbẹ.
27. Fi ẹ̀ṣẹ kún ẹ̀ṣẹ wọn: ki o má si ṣe jẹ ki nwọn ki o wá sinu ododo rẹ.
28. Nù wọn kuro ninu iwe awọn alãye, ki a má si kọwe wọn pẹlu awọn olododo.
29. Ṣugbọn talaka ati ẹni-ikãnu li emi, Ọlọrun jẹ ki igbala rẹ ki o gbé mi leke.
30. Emi o fi orin yìn orukọ Ọlọrun, emi o si fi ọpẹ gbé orukọ rẹ̀ ga.
31. Eyi pẹlu ni yio wù Oluwa jù ọda-malu tabi akọ-malu lọ ti o ni iwo ati bàta ẹsẹ.
32. Awọn onirẹlẹ yio ri eyi, inu wọn o si dùn: ọkàn ẹnyin ti nwá Ọlọrun yio si wà lãye.
33. Nitoriti Oluwa gbohùn awọn talaka, kò si fi oju pa awọn ara tubu rẹ̀ rẹ́.