Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 68:16-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Ẽṣe ti ẹnyin nfi ilara wò, ẹnyin òke, òke na ti Ọlọrun fẹ lati ma gbe? nitõtọ, Oluwa yio ma gbe ibẹ lailai.

17. Ainiye ni kẹkẹ́ ogun Ọlọrun, ani ẹgbẹrun ati ẹgbẹgbẹrun: Oluwa mbẹ larin wọn, ni Sinai ni ibi mimọ́ nì.

18. Iwọ ti gòke si ibi giga, iwọ ti di igbekun ni igbekun lọ: iwọ ti gbà ẹ̀bun fun enia: nitõtọ, fun awọn ọlọtẹ̀ pẹlu, ki Oluwa Ọlọrun ki o le ma ba wọn gbe.

19. Olubukún li Oluwa, ẹni ti o nba wa gbé ẹrù wa lojojumọ; Ọlọrun ni igbala wa.

20. Ẹniti iṣe Ọlọrun wa li Ọlọrun igbala; ati lọwọ Jehofah Oluwa, li amúwa lọwọ ikú wà.

21. Nitori Ọlọrun yio fọ ori awọn ọta rẹ̀, ati agbari onirun ti iru ẹniti nrìn sibẹ ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀.

22. Oluwa wipe, emi o tun mu pada lati Baṣani wá, emi o tun mu wọn pada lati ibu okun wá.

23. Ki ẹsẹ rẹ ki o le pọ́n ninu ẹ̀jẹ awọn ọta rẹ, ati àhọn awọn aja rẹ ninu rẹ̀ na.

24. Nwọn ti ri ìrin rẹ, Ọlọrun; ani ìrin Ọlọrun mi, Ọba mi, ninu ibi mimọ́ nì.

25. Awọn akọrin lọ niwaju, awọn olohun-elo orin kẹhin; larin awọn ọmọbinrin ti nwọn nlu ìlu.

26. Ẹ fi ibukún fun Ọlọrun li ẹgbẹgbẹ, ani fun Oluwa, ẹnyin ti o ti orisun Israeli wá.

27. Nibẹ ni Benjamini kekere wà, pẹlu olori wọn, awọn ọmọ-alade Juda pẹlu awọn igbimọ wọn, awọn ọmọ-alade Sebuloni, ati awọn ọmọ-alade Naftali.

28. Ọlọrun rẹ ti paṣẹ agbara rẹ: Ọlọrun fi ẹsẹ eyi ti o ti ṣe fun wa mulẹ.

29. Nitori tempili rẹ ni Jerusalemu li awọn ọba yio ma mu ọrẹ fun ọ wá.

30. Ba awọn ẹranko ẽsu wi, ọ̀pọlọpọ awọn akọ-malu, pẹlu awọn ọmọ-malu enia, titi olukulùku yio fi foribalẹ pẹlu ìwọn fadaka: tú awọn enia ti nṣe inu didùn si ogun ka.

31. Awọn ọmọ-alade yio ti Egipti jade wá; nisisiyi ni Etiopia yio nà ọwọ rẹ̀ si Ọlọrun.

32. Ẹ kọrin si Ọlọrun, ẹnyin ijọba aiye; ẹ kọrin iyìn si Oluwa.

33. Si ẹniti ngùn ati ọrun de ọrun atijọ; wò o, o fọhùn rẹ̀, eyi na li ohùn nla.

34. Ẹ jẹwọ agbara fun Ọlọrun; ọlá-nla rẹ̀ wà lori Israeli, ati agbara rẹ̀ mbẹ li awọsanma.

35. Ọlọrun, iwọ li ẹ̀ru lati ibi mimọ́ rẹ wọnni wá: Ọlọrun Israeli li On, ti nfi ilera ati agbara fun awọn enia rẹ̀. Olubukún li Ọlọrun!

Ka pipe ipin O. Daf 68