Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 65:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ỌLỌRUN, iyìn duro jẹ de ọ ni Sioni: ati si ọ li a o mu ileri ifẹ nì ṣẹ.

2. Iwọ ti ngbọ́ adura, si ọdọ rẹ ni gbogbo enia mbọ̀.

3. Ọ̀ran aiṣedede bori mi: bi o ṣe ti irekọja wa ni, iwọ ni yio wẹ̀ wọn nù kuro.

4. Alabukún-fun li ẹniti iwọ yàn, ti iwọ si mu lati ma sunmọ ọdọ rẹ, ki o le ma gbe inu agbala rẹ wọnni: ore inu ile rẹ yio tẹ́ wa lọrùn, ani ti tempili mimọ́ rẹ.

5. Ohun iyanu nipa ododo ni iwọ fi da wa lohùn, Ọlọrun igbala wa: ẹniti iṣe igbẹkẹle gbogbo opin aiye, ati awọn ti o jina réré si okun.

6. Nipa agbara rẹ̀ ẹniti o fi idi òke nla mulẹ ṣinṣin; ti a fi agbara dì li àmure:

7. Ẹniti o pa ariwo okun mọ́ rọrọ, ariwo riru-omi wọn, ati gìrìgìrì awọn enia.

8. Awọn pẹlu ti ngbe apa ipẹkun mbẹ̀ru nitori àmi rẹ wọnni: iwọ mu ijade owurọ ati ti aṣalẹ yọ̀.

9. Iwọ bẹ aiye wò, o si bomi rin i: iwọ mu u li ọrọ̀, odò Ọlọrun kún fun omi: iwọ pèse ọkàn wọn, nigbati iwọ ti pèse ilẹ bẹ̃.

Ka pipe ipin O. Daf 65