Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 64:4-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Ki nwọn ki o le ma tafà ni ìkọkọ si awọn ti o pé: lojiji ni nwọn tafa si i, nwọn kò si bẹ̀ru.

5. Nwọn gba ara wọn niyanju li ọ̀ran buburu: nwọn gbìmọ ati dẹkun silẹ nikọ̀kọ; nwọn wipe, Tani yio ri wọn?

6. Nwọn gbero ẹ̀ṣẹ; nwọn wipe, awa ti pari ero ti a gbà tan: ati ìro inu olukuluku wọn, ati aiya wọn, o jinlẹ.

7. Ṣugbọn Ọlọrun yio tafà si wọn lojiji; nwọn o si gbọgbẹ.

8. Bẹ̃ni ahọn wọn yio mu wọn ṣubu lu ara wọn: gbogbo ẹniti o ri wọn yio mì ori wọn.

9. Ati gbogbo enia ni yio ma bẹ̀ru, nwọn o si ma sọ̀rọ iṣẹ Ọlọrun; nitoriti nwọn o fi ọgbọ́n rò iṣẹ rẹ̀.

10. Olododo yio ma yọ̀ nipa ti Oluwa, yio si ma gbẹkẹle e; ati gbogbo ẹni-iduro-ṣinṣin li aiya ni yio ma ṣogo.

Ka pipe ipin O. Daf 64