Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 64:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ỌLỌRUN, gbohùn mi ninu aroye mi: pa ẹmi mi mọ́ lọwọ ẹ̀ru ọta nì.

2. Pa mi mọ́ lọwọ ìmọ ìkọkọ awọn enia buburu: lọwọ irukerudo awọn oniṣẹ-ẹ̀ṣẹ.

3. Ẹniti npọ̀n ahọn wọn bi ẹnipe idà, ti nwọn si fa ọrun wọn le lati tafa wọn, ani ọ̀rọ kikoro:

4. Ki nwọn ki o le ma tafà ni ìkọkọ si awọn ti o pé: lojiji ni nwọn tafa si i, nwọn kò si bẹ̀ru.

5. Nwọn gba ara wọn niyanju li ọ̀ran buburu: nwọn gbìmọ ati dẹkun silẹ nikọ̀kọ; nwọn wipe, Tani yio ri wọn?

Ka pipe ipin O. Daf 64