Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 62:8-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Gbẹkẹle e nigbagbogbo; ẹnyin enia, tú ọkàn nyin jade niwaju rẹ̀; Ọlọrun àbo fun wa.

9. Nitõtọ asan li awọn ọmọ enia, eke si li awọn oloyè. Nwọn gòke ninu ìwọn, bakanna ni nwọn fẹrẹ jù asan lọ.

10. Máṣe gbẹkẹle inilara, ki o má si ṣe gberaga li olè jija: bi ọrọ̀ ba npọ̀ si i, máṣe gbe ọkàn nyin le e.

11. Ọlọrun ti sọ̀rọ lẹ̃kan; lẹ̃rinkeji ni mo gbọ́ eyi pe: ti Ọlọrun li agbara.

12. Pẹlupẹlu, Oluwa, tirẹ li ãnu: nitoriti iwọ san a fun olukulùku enia gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀.

Ka pipe ipin O. Daf 62