Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 60:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ỌLỌRUN, iwọ ti ṣa wa tì, iwọ ti tú wa ka, inu rẹ ti bajẹ; tún ara rẹ yipada si wa.

2. Iwọ ti mu ilẹ warìri; iwọ ti fọ ọ: mu fifọ rẹ̀ bọ̀ sipò: nitoriti o nmì.

3. Iwọ ti fi ohun ti o ṣoro hàn awọn enia rẹ: iwọ mu wa mu ọti-waini itagbọngbọn.

4. Iwọ ti fi ọpagun fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ, ki a le ma fi i hàn nitori otitọ.

5. Ki a le gbà awọn olufẹ rẹ là; fi ọwọ ọtún rẹ ṣe igbala, ki o si gbohùn mi.

6. Ọlọrun ti sọ̀rọ ninu ìwa-mimọ́ rẹ̀ pe; Emi o yọ̀, emi o pin Ṣekemu, emi o si wọ̀n afonifoji Sukkotu.

7. Ti emi ni Gileadi, ti emi ni Manasse; Efraimu pẹlu li agbara ori mi; Juda li olofin mi;

8. Moabu li ikoko-iwẹsẹ mi; lori Edomu li emi o bọ́ bàta mi si: Filistia ma ho iho ayọ̀ fun mi!

9. Tani yio mu mi wá sinu ilu olodi nì? tani yio sin mi lọ si Edomu?

10. Iwọ ha kọ́, Ọlọrun, ẹniti o ṣa wa tì? ati iwọ, Ọlọrun, ti kò ba ogun wa jade lọ?

11. Fun wa ni iranlọwọ ninu ipọnju: nitori pe asan ni iranlọwọ enia.

12. Nipasẹ Ọlọrun li awa o ṣe akin: nitori on ni yio tẹ̀ awọn ọta wa mọlẹ.

Ka pipe ipin O. Daf 60