Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 6:2-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Oluwa, ṣãnu fun mi; nitori ailera mi: Oluwa, mu mi lara da; nitori ti ara kan egungun mi.

3. Ara kan ọkàn mi gogo pẹlu: ṣugbọn iwọ, Oluwa, yio ti pẹ to!

4. Pada, Oluwa, gbà ọkàn mi: gbà mi là nitori ãnu rẹ.

5. Nitoriti kò si iranti rẹ ninu okú: ninu isa okú tani yio dupẹ fun ọ?

6. Agara ikerora mi da mi: li oru gbogbo li emi nmu ẹní mi fó li oju omi; emi fi omije mi rin ibusùn mi.

7. Oju mi bajẹ tan nitori ibinujẹ; o di ogbó tan nitori gbogbo awọn ọta mi.

8. Ẹ lọ kuro lọdọ mi, gbogbo ẹnyin oniṣẹ ẹ̀ṣẹ; nitori ti Oluwa gbọ́ ohùn ẹkún mi.

9. Oluwa gbọ́ ẹ̀bẹ mi; Oluwa yio gbà adura mi.

10. Oju yio tì gbogbo awọn ọta mi, ara yio sì kan wọn gogo: nwọn o pada, oju yio tì wọn lojíji.

Ka pipe ipin O. Daf 6