Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 59:10-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Ọlọrun ãnu mi ni yio ṣaju mi: Ọlọrun yio jẹ ki emi ri ifẹ mi lara awọn ọta mi.

11. Máṣe pa wọn, ki awọn enia mi ki o má ba gbagbe: tú wọn ká nipa agbara rẹ; ki o si sọ̀ wọn kalẹ, Oluwa asà wa.

12. Nitori ẹ̀ṣẹ ẹnu wọn ni ọ̀rọ ète wọn, ki a mu wọn ninu igberaga wọn: ati nitori ẽbu ati èke ti nwọn nṣe.

13. Run wọn ni ibinu, run wọn, ki nwọn ki o má ṣe si mọ́: ki o si jẹ ki nwọn ki o mọ̀ pe, Ọlọrun li olori ni Jakobu titi o fi de opin aiye.

14. Ati li aṣalẹ jẹ ki nwọn ki o pada; ki nwọn ki o pariwo bi ajá, ki nwọn ki o si ma yi ilu na ka kiri.

15. Jẹ ki nwọn ki o ma rìn soke rìn sodò fun ohun jijẹ, bi nwọn kò ba yó, nwọn o duro ni gbogbo oru na.

16. Ṣugbọn emi o kọrin agbara rẹ; nitõtọ, emi o kọrin ãnu rẹ kikan li owurọ: nitori pe iwọ li o ti nṣe àbo ati ibi-asala mi li ọjọ ipọnju mi.

17. Iwọ, agbara mi, li emi o kọrin si: nitori Ọlọrun li àbo mi, Ọlọrun ánu mi!

Ka pipe ipin O. Daf 59