Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 58:7-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ki nwọn ki o yọ́ danu bi omi ti nṣàn nigbagbogbo: nigbati o ba fa ọrun lati tafà rẹ̀, ki nwọn ki o dabi ẹnipe a ke wọn ni ijanja.

8. Bi igbín ti a tẹ̀ rẹ́ ti o si ṣegbe: bi iṣẹnu obinrin, bẹ̃ni ki nwọn ki o má ṣe ri õrùn.

9. Ki ikoko nyin ki o to mọ̀ igbona ẹgún, iba tutu iba ma jo, yio fi iji gbá wọn lọ.

10. Olododo yio yọ̀ nigbati o ba ri ẹsan na: yio si wẹ̀ ẹsẹ rẹ̀ ninu ẹ̀jẹ awọn enia buburu.

11. Bẹ̃li enia o si wipe, Lõtọ, ère mbẹ fun olododo: lõtọ, on li Ọlọrun ti o nṣe idajọ ni aiye.

Ka pipe ipin O. Daf 58