Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 57:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ṢÃNU fun mi: Ọlọrun, ṣãnu fun mi: nitoriti ọkàn mi gbẹkẹle ọ: lõtọ, li ojiji iyẹ-apa rẹ li emi o fi ṣe àbo mi, titi wahala wọnyi yio fi rekọja.

2. Emi o kigbe pe Ọlọrun Ọga-ogo; si Ọlọrun ti o ṣe ohun gbogbo fun mi.

3. On o ranṣẹ lati ọrun wá, yio si gbà mi bi ẹniti nfẹ gbe mi mì tilẹ nkẹgàn mi. Ọlọrun yio rán ãnu rẹ̀ ati otitọ rẹ̀ jade.

4. Ọkàn mi wà lãrin awọn kiniun: emi tilẹ dubulẹ lãrin awọn ti o gbiná, eyinì ni awọn ọmọ enia, ehín ẹniti iṣe ọ̀kọ ati ọfa, ati ahọn wọn, idà mimú.

5. Gbigbega ni ọ, Ọlọrun, jù ọrun lọ; ati ogo rẹ jù gbogbo aiye lọ.

6. Nwọn ti ta àwọn silẹ fun ẹsẹ mi: nwọn tẹ ori ọkàn mi ba: nwọn ti wà iho silẹ niwaju mi, li ãrin eyina li awọn tikarawọn jìn si.

7. Ọkàn mi ti mura, Ọlọrun, ọkàn mi ti mura: emi o kọrin, emi o si ma kọrin iyìn.

8. Jí, iwọ ogo mi; jí, ohun-èlo orin ati duru: emi tikarami yio si jí ni kutukutu.

9. Emi o ma yìn ọ, Oluwa lãrin awọn enia: emi o si ma kọrin si ọ lãrin awọn orilẹ-ède.

10. Nitoriti ãnu rẹ pọ̀ de ọrun, ati otitọ rẹ de awọsanma.

11. Gbigbega ni ọ, Ọlọrun, jù awọn ọrun lọ ati ogo rẹ jù gbogbo aiye lọ.

Ka pipe ipin O. Daf 57