Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 55:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. FETI si adura mi, Ọlọrun; má si ṣe fi ara rẹ pamọ kuro ninu ẹ̀bẹ mi.

2. Fiye si mi, ki o si da mi lohùn: ara mi kò lelẹ ninu aroye mi, emi si npariwo;

3. Nitori ohùn ọta nì, nitori inilara enia buburu: nitoriti nwọn mu ibi ba mi, ati ni ibinu, nwọn dẹkun fun mi.

4. Aiya dùn mi gidigidi ninu mi: ipaiya ikú si ṣubu lù mi.

5. Ibẹ̀ru ati ìwárìrì wá si ara mi, ati ibẹ̀ru ikú bò mi mọlẹ.

6. Emi si wipe, A! iba ṣe pe emi ni iyẹ-apa bi àdaba! emi iba fò lọ, emi a si simi.

7. Kiyesi i, emi iba rìn lọ si ọ̀na jijin rére, emi a si ma gbe li aginju.

8. Emi iba yara sa asala mi kuro ninu ẹfufu lile ati iji na.

9. Oluwa, ṣe iparun, ki o si yà wọn li ahọn: nitori ti mo ri ìwa agbara ati ijà ni ilu na.

Ka pipe ipin O. Daf 55