Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 50:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ỌLỌRUN Olodumare, ani Oluwa li o ti sọ̀rọ, o si pè aiye lati ìla-õrun wá titi o fi de ìwọ rẹ̀.

2. Lati Sioni wá, pipé ẹwà, Ọlọrun ti tan imọlẹ.

3. Ọlọrun wa mbọ̀, kì yio si dakẹ; iná yio ma jó niwaju rẹ̀, ẹfufu lile yio si ma ja yi i ka kiri.

4. Yio si kọ si awọn ọrun lati òke wá, ati si aiye, ki o le ma ṣe idajọ awọn enia rẹ̀.

5. Kó awọn enia mimọ́ mi jọ pọ̀ si ọdọ mi: awọn ti o fi ẹbọ ba mi da majẹmu.

6. Awọn ọrun yio si sọ̀rọ ododo rẹ̀: nitori Ọlọrun tikararẹ̀ li onidajọ.

7. Ẹ gbọ́, ẹnyin enia mi, emi o si sọ̀rọ; Israeli, emi o si jẹri si ọ: emi li Ọlọrun, ani Ọlọrun rẹ.

8. Emi kì yio ba ọ wi nitori ẹbọ rẹ, ọrẹ-ẹbọ sisun rẹ wà niwaju mi nigbagbogbo.

9. Emi kì yio mu akọ-malu lati ile rẹ jade, tabi obukọ ninu agbo-ẹran rẹ:

10. Nitori gbogbo ẹran igbo ni ti emi, ati ẹrankẹran lori ẹgbẹrun òke.

11. Emi mọ̀ gbogbo ẹiyẹ awọn oke nla: ati ẹranko igbẹ ni ti emi.

Ka pipe ipin O. Daf 50