Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 49:12-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Ṣugbọn enia ti o wà ninu ọlá kò duro pẹ: o dabi ẹranko ti o ṣegbé.

13. Ipa ọ̀na wọn yi ni igbẹkẹle wọn: ọ̀rọ wọn si tọ́ li oju awọn ọmọ wọn.

14. Bi agutan li a ntẹ wọn si isa-okú: ikú yio jẹun lara wọn; ẹni diduro-ṣinṣin ni yio jọba wọn li owurọ; ẹwà wọn yio si rẹ̀ kuro, isa-okú si ni ibugbe wọn.

15. Ṣugbọn Ọlọrun ni yio rà ọkàn mi lọwọ isa-okú: nitoripe on o gbà mi.

16. Iwọ máṣe bẹ̀ru, nitori ẹnikan di ọlọrọ̀, nitori iyìn ile rẹ̀ npọ̀ si i.

17. Nitoripe, igbati o ba kú, kì yio kó ohun kan lọ: ogo rẹ̀ kì yio sọkalẹ tọ̀ ọ lẹhin lọ.

18. Nigbati o wà lãye bi o tilẹ nsure fun ọkàn ara rẹ̀: ti awọn enia nyìn ọ, nigbati iwọ nṣe rere fun ara rẹ.

19. Ọkàn yio lọ si ọdọ iran awọn baba rẹ̀; nwọn kì yio ri imọlẹ lailai.

20. Ọkunrin ti o wà ninu ọlá, ti kò moye, o dabi ẹranko ti o ṣegbe.

Ka pipe ipin O. Daf 49